Biology In Yoruba

Biology In Yoruba

Share

We're Nurturing healthier generation by teaching Biological & Medical sciences on radio in YORUBA Language, bridging gap between science & daily life.

We inform, empower, turn listeners into ambassadors of knowledge through grassroots education since 2018

11/06/2026

Video: Endoskeleton - Eegun inú is the type of skeleton humans possess. In this Video, it's explained in Yoruba Language.

18/05/2026

Eégún Agbárí (The skull) explained in Yoruba Language.

゚viralシfypシ゚

14/05/2026

What is Skeletal System?

Ètò Eégún Ara tàbí Férémù Ara.

Let's learn Skeletal system of the earthworm in YORUBA Language.

13/04/2026

The Circulatory System in Yorùbá (Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìtànká ẹ̀jẹ̀ nínú ìṣàn ènìyàn)

‎Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, orísirísi àwọn oun tó wà láyé ló máa ń jẹ́ kàyéfì fún wa. Ká bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹranko, tó fi mọ àwọn ewéko. Àwọn oun mérìrí pọ̀ ní Abẹ́ Ọ̀run. Kí a wòye lórí ilẹ̀ bí ó ṣe fẹ̀ tó, a ó ri pé àwọn àpáta Rìbìtì so ayé pọ̀ ní ìgbèrí Òkun, ìgbèrí Ọ̀sà. Àrà ni Olódùmarè fi gbogbo oun dá. Tí a bá wo inú ara àwa ènìyàn, àti àwọn Ẹranko, a máa rí àwọn oun àrà ọ̀tọ̀ nínú ara wa náà. Bẹ̀rẹ̀ láti bí a ṣe ń mi, dórí Ètò Ọ́ọ̀lọ̀ oúnjẹ. Ó ṣe mí ní kàyéfì wípé àwa ènìà kò kíyèsí àwọn ẹ̀yà ara wa, kí a mọ bí wọn ṣe ń ṣiṣẹ́, kí á le mọ Ìtọ́jú wọn. Kò yẹ kí ó jẹ́ pé ìgbátí àárẹ̀ tàbí àmódi bá ṣe wá ni ó yẹ kí á máa sáré tọ ilé Ìwòsàn lọ.

‎Tí a bá mọ bí ara wa ṣe ń ṣiṣẹ́, yóò rọrùn fún wa láti mọ Ìtọ́jú rẹ̀ tí àìsàn kò fi ní máa gbé wa de nígbà gbogbo. Kódà tí a a bá dé ilé ìwòsàn, tí dókítà bi wá léèrè oun tó ṣe wá, tí a bá ní ìmọ̀ nípa àwọn Ẹ̀yà ara wa, ó máa rọrùn fún wa láti ṣe àlàyé fún Dókítà irú ibi tí nkan ti ń ṣe wá. Kìí ṣe Dókítà nìkan ló yẹ kó mọ nípa àwọn ẹ̀yà ara wa. Àwa náà lẹ́tọ̀ sí ìmọ̀ yìí.



‎Kí àwọn Ọkọ̀ le rìn, àwa ènìyàn fi ọgbọ́n Orí ṣètò òpópónà oríṣiríṣi fun wọn. Nínú ara àwa ènìyàn tí a jẹ́ Ìsẹ̀dá Eléegun Ẹ̀yìn, àwọn òpópónà wà ní oríṣiríṣi, bákan náà ni àwọn ọlọ́kọ̀ kò gbẹ́hìn nínú ara wa. Tí a bá jẹun, tí a mu omi, tí a fín afẹ́fẹ́ sínú, ǹjẹ́ kí ni ó ń gbé wọn lọ sí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara yòókù? Nínú ìlú àti ní agbègbè, àwọn wáyà àgbéjáde wá káàkiri láti mú iná rìn nílé-sílé. Nínú Ara wá náà, àwọn òpónà wá fún àwọn èròjà láti rìn láti ibì kan bọ́ sí ibòmíràn. Bẹ̀rẹ̀ láti orí Ẹ̀jẹ̀, dé Ọkàn àti àwọn ìṣàn agbẹ́jẹ̀, àwọn ẹ̀yà ara yìí ni iṣẹ́ pàtàkì tí wọn máa ń ṣe fún ara wa lati Tan Ẹ̀jẹ̀ àti àwọn èròjà yòókù kiri ara.



‎Kódà àwọn ẹ̀yà ara yìí máa ń bá àwa ènìyàn yọ ìdọ̀tí ara. Ọ̀nà wo ni wọ́n máa ń gbà láti yọ àwọn ìdọ̀tí tàbí gbé àwọn èròjà tó wúlò kiri ara? Ti ẹ bá fẹ́ gbé ọjà tàbí epo láti Ìpínlẹ̀ Èkó lọ sí ìpínlẹ̀ Òsun, ọkọ Àjàgbé Ejò ni ẹ máa wà, tàbí ọkọ̀ kékeré mìíràn fún epo tí kò pọ̀. Nínú ara, Ẹ̀jẹ̀ ló máa ń ṣiṣẹ́ a gbẹ́ èròjà kiri gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ Àjàgbé yìí. Ẹ̀jẹ̀ kìí dá iṣẹ́ ṣe, ó nílò àwọn Alàbàrù láti ba gbe àwọn èròjà yìí. Àwọn òpópónà tí ẹ̀jẹ̀ máa tọ̀ láti rìn káàkiri ara ní ISAN AGBẸ́JẸ̀.

‎Ara jẹ́ ibùdó tó gbòòrò púpọ̀, ayé kan ni inú ara àwa ènìyàn jẹ́. Bí a ṣe ní Ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́kọ̀ àwọn èròjà nínú ara, tí a sì ní àwọn Òpójẹ̀/Isan Àgbẹ́jẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi òpópónà fún ẹ̀jẹ̀, a tún wà ní Ẹ̀yà ara kan tó jẹ́ alàgbàra púpọ̀. Ẹ̀yà ara yìí gaan ni ó máa ń ṣiṣẹ́ jù nínú ara. Ẹ̀yà ara yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ara. ỌKÀN ni ẹ̀yà ara yìí ń jẹ́. Kí ni Ọkàn? Kí ni ìwúlò Ọkàn? Tí a bá kọ́ ilé, tí a fẹ́ kí omi lílò di ìrọ̀rùn fún wa láti lò, ṣe bí ẹ̀rọ Afami-gbómi-wọlé ni a máa ń lò?

‎Ọkàn tó wà nínú Igbá àyà àwa ènìyàn ni ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀rọ Afami-gbómi-wọlé nínú ara wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ẹ̀jẹ̀ ni òun máa ń tàn káàkiri ara. Ọkàn je ẹ̀yà ara to jẹ́ kìkì iṣu ara. Àwọn isu ara yìí àti àwọn ẹ̀yà mìíràn ló gbé Ọkàn dúró. Ọkàn kìí dá ọwọ́ iṣẹ́ dúró rárá àyàfi tí ìṣòro bá dé báa. Bákan náà ni ẹ̀jẹ̀ kìí fi isan agbẹ́jẹ̀ sílẹ rárá. Gbogbo ẹ̀jẹ̀ àti àwọn èròjà tí ẹ̀jẹ̀ máa ń gbé gbọ́dọ̀ gba inú isan agbẹ́jẹ̀ kọjá ní.

09/04/2026

Video: Neurotransmitters are called Alátagba Inú ọpọlọ in Yoruba Language, this video explains what they are and their functions.

06/04/2026

Ọ̀pọ̀lọ́ ò jọ Kọ̀nkọ̀, ṣé lóòótọ́ ni? (Differences between the Toad and the Frog explained in Yoruba Language)


Owe Yoruba sọ pe "ti a ba gbe ọpọlọ, ti o jọ kọnkọ, a maa n fi silẹ ni", bi o ti lẹ jẹ pe ọpọlọ ati kọnkọ jọ ara wọn ni awọn ọna kan, owe yii fidi ẹ mulẹ pe wọn yatọ si ara wọn ni ọpọlọpọ ọna. Njẹ owe yii fi mulẹ pe awọn Yoruba naa ni imọ ijinlẹ ti wọn lapa kan sugbọn ti ko si akọsilẹ to pọ nipa ẹ. Ki ni imọ ijinlẹ sọ nipa iyatọ laarin ọpọlọ ati kọnkọ? Iru ẹranko wo gaan ni wọn jẹ? Ibo ni wọn n gbe? Ẹ jẹ ka jọ rin irin ajo wọnu imọ ijinlẹ nipa awọn isẹmi!

Ti a ba kọkọ fo ju kan ọpọlọ pẹlu kọnkọ, bakan naa la maa ro pe wọn jẹ. Sugbọn ti a ba tẹju mọ wọn daadaa, ti a kiyesi awọn irisi ati adamọ kan, a o ri awọn iyatọ to yani lẹnu pupọ. Igbe aye wọn yatọ gedegbe bakan naa. Ẹ jẹ ka satupalẹ awọn oun amujọ ara ẹni laarin ọpọlọ ati kọnkọ. Ninu imọ isẹmi ti a tun n pe ni baọlọji, wọn ni gbogbo kọnkọ ni ọpọlọ. Ki lo bi iru ipinnu imọ yii? Idi ni pe wọn ka ọpọlọ ati kọnkọ si ẹranko ti ko ni iru. Ẹbi ni ọpọlọ ati kọnkọ jẹ, ti wọn si pin awọn iwa orisirisi ni afijọ. Ki a bẹrẹ lati ori ipin wọn, isẹda agbomi gbelẹ tun ni wọn. Wọn maa n bẹrẹ aye wọn gẹgẹ bii tanwiji ninu omi, ti wọn dẹ maa n dagba lati ni fuku ati awọ to maa ran wọn lọwọ lati mi lori ilẹ. Ẹranko ẹlẹjẹ tutu ni ọpọlọ ati kọnkọ jẹ nitori wọn rọgbọku le agbara oorun lati pese ooru ara fun wọn. Ẹranko ajẹran tun ni awọn mejeji, nitori pe wọn maa n lo ahọn wọn to gun lati dọdẹ awon kokoro fun jijẹ. Ẹranko ni imọ ijinlẹ ka awọn kokoro si. Iran kọnkọ ati ọpọlọ fọn ka orilẹ aye ni.

Ti a ba wo awọ ọpọlọ ati kọnkọ si ara wọn, iyatọ gedegbe wa o. Ara kọnkọ maa n jọlọ daadaa, to si maa n laagun tabi ni omi diẹ lori awọ rẹ. Bakannaa ni ara kọnkọ maa n ri wakuku pẹlu isan diẹ. Nitori pe ara kọnkọ o gbọdọ gbẹ furu-furu, wọn ni lati maa wa nitosi omi ni ọpọ igba fun iwa laaye. Awọn ọpọlọ ni awọ to gbẹ, ara wọn yi tikẹ tikẹ to si maa n gbe omi pamọ. Wọn ni eyi to fara jọ apa lara eyi ti ko mu ara wọn jọlọ kankan. Awọn eyi ti wọn ni lara ni imọ ijinlẹ fi idi ẹ mulẹ gẹgẹ bi asun oje(asunje). Awọn ọpọlọ le gbe aye ni bi ti omi o ti pọ pupọ nitori pe ara wọn gbẹ ju ti kọnkọ lọ. Awọn ọpọlọ maa n sanra, ti wọn dẹ maa n kuru si kọnkọ.

Nini irinkerindo awọn ẹranko mejeji, a maa kiyesi pe kọnkọ mọ ere sa, o si le fo daadaa ju ọpọlọ lọ. Awọn kọnkọ ni ẹsẹ to gun, to dẹ ni agbara, eyi lo ro wọn ni agbara lati le fo, ati luwẹ ninu omi. Ọpọlọ o sare daadaa, wọn maa n fo gẹgẹ bi alailagbara ni, tori wọn sanra ti ẹsẹ wọn dẹ kuru. Awọn ọpọlọ kii saba luwẹ ninu omi, o pe wọn ki wọn o rakoro. Awọn ọpọlọ maa n ye ẹyin wọn ni ilana to da bi ẹwọn (ṣeeni) sugbọn ti ẹyin awọn kọnkọ maa n dipọ. O pọn dandan fun kọnkọ lati maa wa nitosi omi.

Njẹ Kọnkọ ati Ọpọlọ ṣee jẹ? Imọjinlẹ fi ye wa pe nse lo yẹ ki a yago fun jijẹ awọn mejeeji nitori pe o maa n nira lati mọ eyi to ni tabi ti ko ni Majele ninu wọn.

Ti a ba gbe mejeeji yẹ wo, orisirisi awọn ẹya Lagbaye ni wọn maa n jẹ kọnkọ nitori pe o maa n pese mundunmundun apese ẹjẹ ti a mọ si puroteeni. Iwadi fi han pe awọn ọpọlọ lo ni majele oloro julọ. Awọn ọpọlọ ni asunje kan lẹgbẹ oju wọn to fun lagbara lati le tu oro jade nibẹ to le mu ojojo ba awọn isẹda abẹmi bi o tilẹ jẹ pe Fun aabo ara ni ọpọlọ maa n lo asunje naa fun. Ko si iwadi kankan to sọ pe jijẹ ọpọlọ le fa aisan warapa amọ o le fa giri nitori awọn majele ara ẹ.

Bawo ni a sele da ọpọlọ mọ yatọ si kọnkọ ninu oko?
Ẹba odo ni a ti maa n saba ri kọnkọ pẹlu ẹsẹ wọn to maa kajọ ni igbaradi lati fo sinu akuọ ti wọn n gbe. Iran awọn kọnkọ po ti a maa n pe awọn kan ni pọntan, tabi onto. Bi irisi awọ wọn ṣe ri ni Yoruba fi maa n sọ wọn lorukọ.

Ọpọlọ maa n wa ni ilẹ gbigbẹ, inu igbo ti ko diju pupọ naa, pẹlu ẹsẹ wọn puturu, ati ara to sanra, wọn kii le fo pupọ. Iran wọn pọ bakannaa ti awọn kan maa n jẹ ekute. Lóòótọ́, Ọpọlọ o jọ Kọnkọ!

26/03/2026

Video: Orísun Oyin àti ìpàwọ̀dà Ọ̀gà (Origin of Honey and the changing colour of the chameleon)

This video explains how the bee reproduces and also produce honey. Explained in Yoruba Language. Biology in Yoruba.

Want your school to be the top-listed School/college in Ibadan?

Click here to claim your Sponsored Listing.

Location

Telephone

Website

Address


Orita Basorun Ibadan
Ibadan